Hymn 966
Mo ni ife lati lo ki emi wa lodo Kristi.
Meter: C.M. & Ref.
Scripture: Fili. 1:23
1
fParadise; paradise,
Tani ko fe ’simi,
Tani ko fe ’le ayo na
Ile alabukun.
CHORUS
Ni b’awon oloto
Wa lae ninu ’mole
Won nyo nigbagbogbo
Niwaju Olorun.
2
fParadise! Paradise!
pAye ndarugbo lo.
Tani ko si fe lo simi,
Nib’ife ki tutu.
3
fParadise! Paradise
pMo fe ki nye d’ese
Mo fe ki nwa lodo Jesu
Li ebute mimo.
4
fParadise! Paradise!
Un ko ni duro pe mo
Nisiyi b’enipe mo ngbo
Ohun orin orun.
5
fJesu Oba Paradise
Pa mi mo n’nu ‘fe Re;
Mu mi de ile ayo na,
Nib’isimi l’oke.