Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 974

A gbo kan ati Oluso agutan kan ni yoo si je.

Meter: 7.7.6. & Ref.

Scripture: Jn. 10:16

1

mfNihin l’awa nje ’rora

Nihin ni a ma pinya,

mpL’orun ko si ’pinya

CHORUS

fA! bi o ti dun to!

Dun to, dun to, dun to!

A! bi o ti dun to

Nigbat’a kio pinya mo!

2

mfAwon t’o feran Jesu.

Won o lo s’oke orun.

Lo b’awon t’o ti lo

3

mfOmode y’o wa nibe,

T’o wa Olorun l’aye

Ni gbogbo ’le eko

4

mfOluko, baba, iya,

Won o pade nibe na,

Won ki o pinya mo.

5

ffBi a o ti yo po to!

’Gbat’ a ba r’olugbala

Ni ori ite Re!

6

Nibe l’ao korin ayo,

Titi aye ailopin,

L’a o ma yin Jesu.