Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 976

Jerusalemu mimo, ti nti orun sokale lati odo Olorun wa.

Meter: 8.7.8.7.8.7.

Scripture: Ifi. 21:10

1

fSalem t’orun, ilu ’bukun

T’o kun fun ’fe at’ayo,

Ti a f’okuta aye ko

Ni orun giga loke;

Pel’ogun angeli yika

T’o nsokale b’iyawo.

2

Lat’ode orun lohun wa

L’o ti wo aso ogo

T’o ye Eni ti o fe o;

A o sin o f’oko re;

Gbogbo ita, at’odi Re

Je kiki oso wura.

3

Ilekun re dan fun Pearl,

Won wa ni sisi titi;

Awon oloto nwo ’nu re

Nip’ ejo Olugbala,

Awon t’o farada ’ponju

’Tori oruko Jesu.

4

Wahala at’iponju nla

Le s’okuta re l’ewa;

Jesu papa l’Eni to won

Si ipo ti o dara

Ife inu Re sa ni pe

K’ale s’afin Re l’oso

5

ffOgo at’ola fun Baba

Ogo at’ola f’Omo,

Ogo at’ola fun Emi

Metalokan titi lae

At’ayeraye okan na,

Bakan na titi aye.