Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 979

Oluwa mo awon ti ise Tire.

Meter: 8.7.8.7.

Scripture: II Tim. 2:19

1

mfOba awon eni mimo

T’o mo ’ye awon ’rawo;

Opo eni t’eda gbagbe

Wa yika ite Re lae.

2

mf’Mole ti kuku aye bo

Ntan ’mole roro l’oke

Won je Om-alade l’orun,

Eda gbagbe won l’aye.

3

mfLala at’iya won fun O,

Eda ko r’oyin re mo;

Iwa rere won f’ara sin,

Oluwa nikan l’O mo.

4

diWon f’ara sin fun wa sugbon

A ki won s’iwe iye;

Igbagbo, adura, suru,

Lala on ’jakadi Won.

5

mfWon mo isura Re l’ohun;

Ka wa mo won, Oluwa,

Nigbat’O ba nsiro oso,

Ti mbe l’ara ade Re.