Hymn 981
E wo iru ife ti Baba fi fe wa, ti a fi npe wa ni omo Olorun.
Meter: 7.7.7.D.
Scripture: I Jn. 3:1
1
fAlabukun n’nu Jesu,
Ni awon om’Olorun
Ti a fi eje Re ra
pLat’inu iku s’iye;
crOpe, a ka wa mo won,
L’aye yi, ati l’orun.
2
fK’a to d’aye ni Baba
Fe won ninu Omo Re;
Nipa ’gbagbo n’nu Jesu
Ni won gba edidi yi.
3
fAwon ti a da l’are
Nipa ore ofe Re.
A we gbogbo ese won,
Won o bo l’ojo ’dajo.
4
mpWon ns’eso ore-ofe
Ninu ise ododo,
Irira l’ese si won,
Or’Olorun ngbe ’nu won.
5
Nipa ej’Odagutan,
Won mba Olorun k’egbe
Pelu olanla Jesu.
A wo won l’aso ogo.