Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 982

Gbogbo awon angeli si duro yi ite na.

Meter: D.C.M.

Scripture: Ifi. 7:11

1

fBaba, niwaju ite Re;

L’angeli nteriba;

Nigbagbogbo niwaju Re

Ni won korin iyin;

diWon si nfi ade wura won

Lele yi ’te na ka;

crWon nfi ohun pelu duru

Korin si Oluwa.

2

mfDidan osumare si ntan

Si ara lye won;

crSerafu nke si Serafu

Ti won nkorin ’yin Ite;

pBi a ti kunle nihinyi

Ran ore Re si wa,

K’a mo pe ’wo wa nitosi

Lati da wa lohun

3

mfNihin, nibit’awon angel’

Nwo wa b’a ti nsin O

crKo wa, k’a wa ile orun,

K’a sin O bi ti won;

fK’a ba won ko orin iyin.

K’a ba won mo ’ fe Re:

Titi agbara y’o fi di

Tire, Tire nikan.