Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 983

Mo si gbo ohun awon angeli pupo yi ite na ka.

Meter: C.M

Scripture: Ifi. 5:11

1

fEwa, k’a da orin wa po

Mo t’awon angeli;

Egbegberun ni ohun won

Okan ni ayo won.

2

Won nkorin, pe, Ola nla ye

Od’agutan t’a pa;

K’a gberin pe, Ola nla ye”

pN’tori O ku fun wa.

3

mfJesu li o ye lati gba

Ola at’agbara;

crK’iyin t’enu wa ko le gba

Je Tire, Oluwa.

4

fK’awon t’o wal’oke orun

At’ile at’okun

Dapo lati gb’ogo Re ga,

Jumo yin Ola Re.

5

ffKi gbogbo eda d’ohun po,

Lati yin oruko

Eni t’O joko l’or’ite,

Ki won si wole fun.