Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 986

Nigbati O ba farahan, a o dabi Re.

Meter: 8.7.8.7.8.7.8.7. & Ref.

Scripture: I Jn. 3:2

1

crGbat’ ikuku ba rekoja

T’ojo titun ba si de;

mfTi ’tansan orun farahan

L’or’awon isan omi;

T’a nranti ’leri Baba wa

N’nu didan osumare;

A'o mo ’ra wa ju t’isiyi

’Gbat’ kuku ba koja

CHORUS

fL’owuro ’jo didan ni

Ojo t’o logo julo

A o mo ’ra wa ju t’isiyi

’Gbat’ ikuku ba koja,

Ao mo bi a ti mo wa

Lae ka ma da nikan rin.

2

mpNisiyi, a nrin ajo wa

N’nu aro on isoro;

pNisiyi, a nse wa nise

Nihin at’ibi gbogbo;

crSugbon ao gb’ohun Baba wa

Pe, “E wa, eyin omo”

L’owuro ojo didan ni

Gbat’ ikuku ba koja.

3

f’Gbana okan wa y’o f’ayo

Yi ite ogo Re ka;

A o ri awon t’o fe wa

A o mo b’a ti mo wa

Orin ’rapada wa l ao ko

Titi lae ati laelae,

’Gbat’ isudede ba kuro

T’ikuku si rekoja.