Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 987

Mo si ri ilu mimo ni, Jerusalemu titun, Ilu na si je kiki wura

Meter: 7.6.7.6.D

Scripture: Ifi. 21:2,18

1

mfJerusalem ilu mi

Ti wara, oyin nsan

Itunu ni fun okan

Ti nronu nipa re;

fTani le so ayo nla

Ti nduro de awa

T’a se ye fun ilu na.

Ilu ogo titi?

2

Won duro loke Sion,

ffWon nkorin ayo nla,

Gbogb’ aopn ajeriku

At’awon angeli.

Oluwa mbe larin won;

Ojo tu won lara,

Ilu awon ayanfe.

Ilu ogo julo.

3

Omo Dafidi njoba

ffKo si aniyan mo;

Iho ayo isegun,

Orin irapada;

Awon asegun pelu

Balogun won dapo

Won wo aso isegun

Titi ayeraye.

4

Ilu alabukunfun,

Ile ayanfe Re;

Ilu opo ibukun

F’okan ti npongbe re;

Jesu, jowo se wa ye

Fun ilu isimi

Nibiti Iwo, Baba

Ati Emi gbe wa.