Hymn 989
Awon wonyi li o jade lati inu iponju nla.
Meter: 7.7.7.7.D.
Scripture: Ifi. 7:14
1
mfTal’awon yi t’aso won
Ndan ju orun osan lo?
Asaju omo ’mole.
T’o sunmo ’te Olorun?
Awon yi l’otijiya,
Nitori Oluwa won,
Ati ninu isin Re;
’Won l’o to Kristi leyin.
2
mpWon t’inu iponju wa,
Won feje Od’agutan
Fo ’so won, nipa ’gbagbp
Eje na ti we ni mo;
crNitorina won njosin
Leba ite Eleda;
Olorun si mba won gbe,
Inu Re si yo si won.
3
mfWon ta’won asegun yo,
Idanwo won ti pari;
Gbogbo ise won koja
Ebi, ongbe, ko si mo;
Oru ko mu won, n’tori
Owo orun ko de ’be.
Ilu ’tura ni won ngbe,
Ibi ’mole ailopin.
4
Od’agutan, l’ori ’te,
Y’o ma bo won n’gbagbogbo,
Y’o fonje iye bo won.
Y’o fomi ’ye fun won mu;
Y’o pa ’banuje won re,
Gbogbo aini won y’o tan
Y’o nu omije won nu,
Y’o fife kun okan won.