Hymn 99
Fun Oba ayeraye, aidibaje, airi, Olorun kansoso ni Ola ati ogo wa fun lae ati laelae.
Meter: 11.11.11.11.
Scripture: I Tim. 1:17.
1
mfOba aiku, airi, orisun ogbon
To wa n’nu imole t’oju kole wo,
Olubukun julo, Ologo julo,
Alagbara, 0lusegun, ’WO la yin.
2
Laisimi, laiduro, ni idakeje,
O njoba LO, O ko si se alaini;
Giga ni idajo Re bi oke nla,
Ikuku Re b’isun ire at’ife.
3
fO nte gbogbo eda alaye lori
Nipa imisi Re won ngbe igbe won
A ndagba, a ngbile bi ewe igi
Asi nro; sugbon bakanna l’Olorun
4
fBaba nla Ologo Imole pipe
AWON angeli Re wole l’ese Re
Iyin wa la mu wa, JO ran wa l’owo
K’a ler’ogo imole to yi O ka