Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 993

Awon orun nsoro ogo Olorun, ati ofurufu nfi ise Owo Re han.

Scripture: OD. 19:1

1

pOlorun mi’gbati mo f’iyanu wo

Gbogbo aye t'o ti f’owo Re da

Mo ri ‘rawo, mo gbohun ara ti nsan

Agbara Re han ni gbobgo aye.

CHORUS

mpOkan mi nkorin s'Olugbala mi

Agbara Re ti to tobi to?

Okan mi nkorin s’Olugbala mi

Agbara Re ti tobi to?

2

pPelu 'yanu mo wo ‘se Re l’aginju

Eye nkorin didun lori igi

Mo wo ile lat’ ori oke giga

Mo r’agbara odo at’ afefe

3

pGbati mo ro b’Iwo ti fi Omo Re

Sile lati ku, ko tile ye mi

L'ori agbelebu l’oru ese mi

Eje Re lo ti ki eje mi lo.

4

pGbati Jesu ba de n’nu Ola nla Re

Lati pe mi ayo mi yo ti to

Gbana ni 'rele un o wole lati sin

Un o wipe Olorun ti tobi to.