Hymn 996
E lo si gbogbo aye, ki e si ma wasu ihinrere fun gbogbo eda
Scripture: Mk 16:15
1
fTo asako lo, lo f’ife ro won
Awon t' o sina s' ori oke ,
Wa sodo mi! ni ohun Jesu wi
pGbo b'Oluwa ti mbebe loni.
CHORUS
A nrin ajo lo s' ori oke
Lati pe asako pada (pe pada)
Sinu agbo Olugbala wa
Jesu t’a pa fun elese (pa f’elese)
2
fTo asako lo, fi Jesu han won
Okan are t’o si ti gbogbe
Ma sin won lo si ona igbala
Fi ona iye pipe han won.
3
fK'a ma te siwaju n'ise rere
K'a ma tele Kristi lojojo
Ka ma se 'anu gb'eni subu ro
K'a ma fi Jesu han asako.