Hymn 997
Ko si igbala lodo elomiran nitori ko Si oruko miran labe orun ti a fi fun ni ninu eniyan nipa eyiti a le fi gba wa La.
Scripture: Ise A. 4:12
1
fSa di oruko Jesu mu
N’igba ibanuje re
Y'O si fi itunu fun o
Ro mo ni ibi gbogbo
CHORUS
Oruko...... Iyebiye
Ireti wa l’aye yi
Oruko ....... iyebiye
Ayo fun awon t’orun.
2
fMa fi oruko Jesu se
Asa nigba idanwo
B'idamu kan ba de ba o
F'oruko na gbadura.
3
fMa iyebiye l'ooko Jesu
O nimu ki okan wa yo,
Gbat' apa 'fe Re ba gba wa.
A o korin iyin Re.
4
mfAo juba oruko Jesu
Ao wole li ese Re
Ao de Oba wa l'ade
Gbat' tajo wa ba pari.