Hymn 1
Bùkún 'lé wa àt'ẹbí wa, àt'ara wa
1
Bùkún 'lé wa àt'ẹbí wa, àt'ara wa
Bùkún 'lé wa àt'ẹbí wa, àt'ara wa
Ìbùkún ọ̀run, ìrànwọ́, Rẹ,
Ìbùkún ọ̀run k'O fi kárí àwa,
K'O fi fún wa o, l'áyé l'ọ̀run o,
Baba ọ̀run.
2
Tú wa lára, Alágbára, ṣe 'tọ́jú wa
Tú wa lára, Alágbára, ṣe 'tọ́jú wa
Ìtùnú Rẹ, àlàáfíà Rẹ,
Ìkẹ́ Rẹ, K'O fi tọ́jú wa, yé,
Àwa mbẹ́ O o, gbọ́ àdúrà wa,
Ọba Ògo.
3
Baba fún wa l'Ẹ̀mí mímọ́ àt'agbára
Baba fún wa l'Ẹ̀mí mímọ́ àt'agbára
Ìránṣẹ́ ọ̀run, ẹ̀bùn lát'ọ̀run
Ìtùnú Baba, k'ó wọ inú ọkàn wa,
K'ó gbé 'nú wa o, k'ó fún wa l'ayọ̀,
Ọba Ọ̀run.
4
Àwa f'ìyìn àt'ọpẹ́ fún Baba l'ọ̀run
Àwa f'ìyìn àt'ọpẹ́ fún Baba l'ọ̀run
Ìyìn fún 'rànwọ́, ọpẹ́ fún àánú,
Ayọ̀ fún 'dásí tí a ńrí lójojúmọ́,
Ọpẹ́ fún O o, a tún júbà Rẹ,
Baba àwa.
Àmín.