Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 10

Àwọn ọmọdé ṣ'ẹkà wẹ́wẹ́ àt' imọ́pẹ s'ọ́nà

1

Àwọn ọmọdé ṣ'ẹkà wẹ́wẹ́ àt' imọ́pẹ s'ọ́nà,

Wọ́n sì nké, Hósánà,

Èyí ni orin 'ṣẹ́gun t'a kọ́ wọ́nù Jérúsálẹ́mù

Hósánà! Hósánà!

CHORUS

Èyí l'Ọmọ ńlá Dáfídì àti Ọba Ísírẹ́lì!

Ó gùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ fún ìgbàlà ọmọ ènìyàn,

Hósánà! Hósánà!

Hósánà sí Ọmọ Dáfídì!

2

Àwọn àgbàgbà gbìyànjú láti pa wọ́n l'ẹ́nu mọ́.

Wọ́n tún nké Hósánà;

B'àwọn wọ̀nyí pa ẹnu wọ́n mọ́, òkúta yóò sọ̀rọ̀,

Hósánà! Hósánà!

3

Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Síónì pé Ọba rẹ mbọ̀ wá

Hósánà! Hósánà!

Ó tẹnú, Ó sì jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

Hósánà! Hósánà!

4

Olùbùkún l'Ẹni tí mbọ̀ wá l'orúkọ Olúwa!

Hósánà! Hósánà!

Ẹ tẹ́ ọkàn yín sí ọ̀nà fún Kristi, Ọba Ògo,

Hósánà! Hósánà!

Àmín.