Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 11

Ẹ̀mí Baba Alààyè

1

Ẹ̀mí Baba Alààyè,

Sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú

Agbára Pẹ́ńtíkọ́stì;

Sọ ọkàn wa jí,

Kí O sì mú gbóná;

B'iná ọ̀run, wá

Pẹ̀lú 'tùnú ńlá;

Tan 'mọ́lẹ̀ rẹ.

2

Ayé àti ẹ̀mí wá,

Gbà, fi ṣe Tìrẹ;

Nínú ìsìn wa fún O

K'á ní 'rànwọ́ Rẹ

Láti j'olótìítọ́;

K'ẹ̀bùn àt'ọ̀run

Ti Pẹ́ńtíkọ́stì

Bá s'orí wá.

3

Fi ẹ̀jẹ̀ 'yebíye Rẹ

T'ókè Kálfárì

Wẹ ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ wa nù;

Sì rà wá padà;

Fi 'fẹ́ kún àyà wá,

K'á rìn 'nà òtítọ́

Ìfẹ́ Rẹ l'àó ṣe

Bí ti ọ̀run.

4

Baba, Ọmọ òun Ẹ̀mí,

Mẹ́talọ́kan láé,

Ìyìn, ògo, agbára

Jẹ́ Tìrẹ nìkan;

Ẹ̀wà Rẹ l'áyé yìí,

Yóò jẹ́ ayọ̀ wá

Pẹ̀lú ìdúpẹ́,

Alelúyà!

Àmín.