Hymn 12
A ti mú mi l'aginjù ayé yìí ja
A ti mú mi l'aginjù ayé yìí ja
Lórí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀;
Kò sí ohun kan t'ó wù mí nínú rẹ̀,
A fi Jérúsálẹ́mù t'ọ̀run.
Ọjọ́ mbọ̀ t'a ó dágbére
Fún ayé pé ó digbóṣe;
Ọjọ́ mbọ̀, ará, ọjọ́ mbọ̀
Tí a ó lọ s'ílé wá l'ókè.
Mo dúró, mo wò ọ̀nà Jérúsálẹ́mù,
Ọkàn mi npọ́gbẹ láti dé 'bẹ̀;
Ohunkóhun tí y'ó bá mú 'dènà wá
Mẹ́talọ́kan bá mi mú kúrò.
Ojóojúmọ́ l'ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ mi npadà
Kúrò lọ́dọ̀ Jésù Olúwa;
Jọ̀wọ́, Jésù, f'ẹ̀jẹ̀ mímọ́ Rẹ rà mí,
F'Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ tọ́ mi sọ́nà.
Ayé nti mi síhìn, nwọ́n nti mi sọ́hùn,
Ṣé, nkò ní padà lọ́dọ̀ Jésù;
Mo ṣèlérí láti bá Jésù jọba
Ìlérí náà kò ní tàṣẹ láé.
A ti fi ilé rere Kénáánì hàn mí,
Ẹwà rẹ̀ kò ṣe f'ẹnu ròyìn
Ará, báwo l'ẹ̀yin ó ha ṣe dé 'bẹ̀?
Ọkàn tí kò dé 'bẹ̀ pàdánù.
Ẹ̀yin ará, ẹ bá mi yin Olúwa
T'Ó f'ọ̀nà Àpósítélì hàn mi;
L'ọjọ́ òní mo mọ Jésù l'Ọba mi,
Ó f'Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀ kún 'nú mi.
Jésù, jọ̀wọ́ dì mí mú títí d'ópìn
Kí nlè bá O d'ópìn l'ó dùn jù.
Alelúyà! ẹ yin Jésù l'ẹ́ẹ̀kan sì
Alelúyà! l'orin ìkẹhìn!
Àmín.