Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 13

Fún wa ní 'lé Kristíánì

1

Fún wa ní 'lé Kristíánì

Ilé tí a nkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ilé tí a nlépá 'fẹ́ Baba

Láti 'fẹ́ Rẹ f'ẹwà dé l'ádé.

CHORUS

Ọlọ́run Baba wá

Fún wá n'ílé Kristíánì.

2

Fún wa ní 'lé Kristíánì

Níbití bálé jẹ́ olóòótọ́

Ilé tó bọ́ lọ́wọ́ aṣìṣe

Ilé tí nyọ̀ fún 'fẹ́ àt' orin.

3

Fún wa ní 'lé Kristíánì

Níbit' ìyá nílé b'ayaba

Nfihàn p'ọ̀nà Rẹ ló dára jù

Ilé t'a gb'Olùgbàlà l'áyé.

4

Fún wa ní 'lé Kristíánì

Níbití a ntọ́ àwọn 'mọdé

Láti mọ Kristi tó fẹ́ràn wọ́n

Ilé tí a ntànná àdúrà.

Àmín.