Hymn 14
Nínú ìrìn àjò mi bẹ́ẹ̀ni mo ńkọrin
1
Nínú ìrìn àjò mi bẹ́ẹ̀ni mo ńkọrin
Mo ntọ́ka sí Kálfárì s'ibi ẹ̀jẹ̀ náà
Ìdánwò l'óde nínú l'ọ̀tá gbé dìde
Jésù l'Ó ntọ́ mi lọ ìṣẹ́gun dájú.
CHORUS
A! mo nfẹ́ rí Jésù, Kí nmáa w' ojú Rẹ̀
Kí nmáa kọrin títí, nípa oore Rẹ̀
Ní ìlú ògo ní kí ngbóhùn sókè
Pé mo hò, ìjà tán, mo dé ilé mi.
2
Nínú iṣẹ́ ìsìn mi, b'ókùnkùn bá sú
Un ó tún bò súnmọ́ Jésù y'Ó tan ìmọ́lẹ̀
Èṣù lè gb' ogun tì mí kí nlè sá padà
Jésù l'ó ntọ́ mi lọ, kò s'ewu fún mi.
3
Bí mo tilẹ̀ bọ́ sínú àfonífojì
Ìmọ́lẹ̀ ìtọ́ni Rẹ y'ó mọ́lẹ̀ sí mi
Y'ó na ọwọ́ Rẹ sí mi, y'Ó gbé mi sókè
Un ó máa tẹ̀síwájú b'Ó ti ntọ́ mi lọ.
4
Nígbàtí ìgbì ayé yìí bá nyì lù mí
Mo ní ààbò t'ó dájú lábẹ́ apá Rẹ
Y'Ó máa f'ọwọ́ Rẹ tọ́ mi títí dé òpin
Ọ̀rẹ́ òdodo ni, A! mo ti f'Ẹ́ tó.
Àmín.