Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 15

Ọlọ́run mi 'gbàtí mo f'ìyanu wò

1

Ọlọ́run mi 'gbàtí mo f'ìyanu wò

Gbogbo ayé t'o ti f'ọwọ́ Rẹ dá

Mo rí 'ràwọ̀, mo gbọ́hùn àrá tí nsán

Agbára Rẹ hàn ní gbogbo ayé.

CHORUS

Ọkàn mi nkọrin s'Olùgbàlà mi

Agbára Rẹ ti tó tóbi tó?

Ọkàn mi nkọrin s'Olùgbàlà mi

Agbára Rẹ ti tóbi tó?

2

Pẹ̀lú 'yànu mo wò 'ṣẹ́ Rẹ l'áginjù

Ẹyẹ nkọrin dídùn lórí igi

Mo wò ilẹ̀ lát' orí òkè gíga

Mo r'agbára odò àt' afẹ́fẹ́.

3

Gbàtí mo rò b'Ìwọ ti fi Ọmọ Rẹ

Sílẹ̀ láti kú, kò tilẹ̀ yé mi

L'órí agbélèbú l'órú ẹ̀ṣẹ̀ mi

Ẹ̀jẹ̀ Rẹ ló ti kì ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.

4

Gbàtí Jésù bá dé n'nú Ọlá ńlá Rẹ

Láti pè mí, ayọ̀ mi yóò ti tó

Gbàna ní 'rẹ̀lẹ̀ un ó wólẹ̀ láti sìn

Un ó wípé Ọlọ́run ti tóbi tó.

Àmín.