Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 16

Ọkàn wá kún f'ayọ̀ lónìí

1

Ọkàn wá kún f'ayọ̀ lónìí

A ti r'ọ́nà wúrà náà

Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ntàn l'ọ́nà wá

A ti r'ọ́nà wúrà náà

Ó ti pẹ́ t'àyún Rẹ nyún wa

Lárin ayidayid' ayé

Díẹ̀ ló kù fún wá k' ó bọ̀

K' á tó r'ọ́nà wúrà náà.

CHORUS

Njẹ́ kọrin, kọrin ayọ̀

F'ọkàn ayọ̀ kọrin sókè

Ìmọ́lẹ̀ dé, a dé 'lé wá

A ti r'ọ́nà wúrà náà.

2

A pè wá kúrò l'áyé yìí

A ti r'ọ́nà wúrà náà

Ọ̀rẹ́ wá gbogbo wà níbẹ̀

A ti r'ọ́nà wúrà náà

Àwa jẹ́rìí pé dídùn náà

K'a má tàṣe ìjọba ọ̀run

Pẹ̀lú Jésù a nlọ 'lé wá

A ti r'ọ́nà wúrà náà.

3

Kíún ní 'dánwò wá t'ó kọjá

A ti t'ọ́nà wúrà náà

Ayọ̀ ilé mú k'a gbàgbé

A ti r'ọ́nà wúrà náà

'Jì kùkù kò ní pẹ́ kúrò

Ìfàyàbalẹ̀ yóò sì dé

A ta 'gbokùn, ọkọ̀ sì gúnlẹ̀

A ti r'ọ́nà wúrà náà.

4

Pẹ̀l'ọkàn 'pẹ́ s'Ọlọ́run wá

A ti r'ọ́nà wúrà náà

Lẹ́ẹ̀kan rí tí a ti sọnù

A ti r'ọ́nà wúrà náà

A fẹ́ d'ọ̀dọ̀ Olùgbàlà

Jésù yóò f'ayọ̀ gbà wá

Ó jẹ́ nípa oor'ọ̀fẹ́ nìkan

A ti r' ọ́nà wúrà náà.

5

A dúpẹ́ l'ọ́w' Ọlọ́run wá

Tí p'a r'ọ́nà wúrà náà

Ìyìn, ògo ọpẹ́, ọlá

Fún Baba àti Ọmọ

Àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́

Mẹ́talọ́kan ayérayé

Títí ayé l'a ó máa yìn;

Pé a r'ọ́nà wúrà náà.

6

Ọpẹ́ ní fún O Elìṣádàì

Jèhófà Rófàì ni k'áyin

Alelúyà orin ìyìn

Fún Mẹ́talọ́kan ṣoṣo.

Àmín.