Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 20

Tọ́ asáko lọ, lọ f'ìfẹ́ rọ̀ wọ́n

1

Tọ́ asáko lọ, lọ f'ìfẹ́ rọ̀ wọ́n

Àwọn t' o ṣìnà s' orí òkè,

Wá sọ́dọ̀ mi! ní ohùn Jésù wí

Gbọ́ b'Olúwa ti mbẹ̀bẹ̀ lónìí.

CHORUS

A nrin àjò lọ s' orí òkè

Láti pè asáko padà (pè padà)

Sínú agbo Olùgbàlà wá

Jésù t'a pa fún ẹlẹ́ṣẹ̀ (pa f'ẹlẹ́ṣẹ̀).

2

Tọ́ asáko lọ, fi Jésù hàn wọ́n

Ọkàn arẹ́ t'ó sì ti gbẹgbẹ́

Máa sìn wọ́n lọ sí ọ̀nà ìgbàlà

Fi ọ̀nà ìyè pípé hàn wọ́n.

3

K'a máa tẹ̀síwájú n'iṣẹ́ rere

K'a máa tẹ̀lé Kristi lójojúmọ́

K'a máa ṣe 'àánú gb'ẹni ṣubú rò

K'a máa fi Jésù hàn asáko.

Àmín.