Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 21

Ṣá di orúkọ Jésù mú

1

Ṣá di orúkọ Jésù mú

N'ìgbà ìbànújẹ́ rẹ

Y'Ó sì fi ìtùnú fún ọ

Rọ̀ mọ́ ni ibi gbogbo.

CHORUS

Orúkọ... Ìyebíye

Ìrètí wá l'áyé yìí

Orúkọ ... ìyebíye

Ayọ̀ fún àwọn t'ọ̀run.

2

Máa fi orúkọ Jésù ṣe

Asà nígbà ìdánwò

B'ìdàmú kan bá dé bá ọ

F'orúkọ náà gbàdúrà.

3

Ìyebíye l'ọ́kọ Jésù

Ó nmú kí ọkàn wa yọ̀,

Gbàt' apá 'fẹ́ Rẹ bá gbà wá.

A ó kọrin ìyìn Rẹ.

4

A ó júbà orúkọ Jésù

A ó wólẹ̀ li ẹsẹ̀ Rẹ

A ó dé Ọba wa l'ádé

Gbàt' àjò wá bá parí.

Àmín.