Hymn 23
Ìgbàlà kíkún ní Ọlọ́run ṣe 'lérí
1
Ìgbàlà kíkún ní Ọlọ́run ṣe 'lérí
F'ẹnití ó bá gba Jésù Ọmọ Rẹ gbọ́.
CHORUS
Alelúyà: Ó parí mo gba Ọmọ gbọ́
Mo rí 'gbàlà nínú ẹ̀jẹ̀ Olùgbàlà.
Alelúyà; ó parí mo gba Ọmọ gbọ́.
Mo rí 'gbàlà nínú ẹ̀jẹ̀ Olùgbàlà.
2
Bí ọ̀nà mi tilẹ̀ kún fún ewu púpọ̀
Dájúdájú Jésù yóò mú mi làjà.
3
Olùfẹ́ púpọ̀ ni mo ní l'óde ọ̀run
Nwọ́n wà nínú ògo, èyí sì l'orin wọ́n.
4
Àwọn ọmọdé dúró l'ẹ́gbẹ́ Ọba wọn
Ó ńrẹ́rìn-ín sí wọ́n bí wọ́n ti ńkọrin wọ́n.
5
Wòlíì àt' Ọba wà ní ìpèjọpọ̀ náà
Nwọ́n ńkọrin bí wọ́n ti nlá 'tà wúrà kọjá.
6
Àwa pẹ̀lú ní láti kọ́ n'nú orin náà
Ọ̀rọ̀ orin ìyìn wa títí láé léyìí.
Àmín.