Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 24

Ipè náà ńdùn l'ọ́tùnún àti l'ósì pé

1

Ipè náà ńdùn l'ọ́tùnún àti l'ósì pé

Tan 'mọ́lẹ̀, tan 'mọ́lẹ̀

Ọpọ̀ l'ó nkú láìní ìrètí ọ̀run

Tan 'mọ́lẹ̀ tan 'mọ́lẹ̀.

CHORUS

Tan 'mọ́lẹ̀ ìhìnrere náà

Jẹ́ k' ó tan yí ayé ká

Tan 'mọ́lẹ̀ ìhìnrere náà

Jẹ́ k' ó tan yí ayé ká.

2

Àwọn t'ó wà l' òkùnkùn nké tantan pé

Tan 'mọ́lẹ̀, tan 'mọ́lẹ̀

Mú wọ́n wá jẹ́jẹ́ s' ibi agbélèbú

Tan 'mọ́lẹ̀, tan 'mọ́lẹ̀.

3

Jẹ́ k'a gbàdúrà k' oor' ọ̀fẹ́ lè jọba

Tan 'mọ́lẹ̀, tan 'mọ́lẹ̀

Kí Ẹ̀mí Krist' jọba ní ibi gbogbo

Tan 'mọ́lẹ̀, tan 'mọ́lẹ̀.

4

Jẹ́ k' a tẹ̀ramọ́ iṣẹ́ t'ó l'érè yìí

Tan 'mọ́lẹ̀, tan mọ́lẹ̀

A ó gbádé níkẹhìn bí a f'orítì

Tan 'mọ́lẹ̀, tan mọ́lẹ̀.

Àmín.