Hymn 26
Mo ntẹ̀síwájú l'ọ́nà náà
1
Mo ntẹ̀síwájú l'ọ́nà náà
Mo ngòkè sí i lójojúmọ́
Mo gbàdúrà bí mo ti nlọ
Olúwa jọ̀ọ́ gbé mi sókè.
CHORUS
Olúwa, jọ̀ọ́ gbé mi sókè
Fà mí lọ sí ibi gíga
Apata t'ó ga jù mí lọ
Olúwa jọ̀ọ́ gbé mi sókè.
2
Ìfẹ́ ọkàn mi kò kúrò
Lárin 'yèméjì àt'ẹ̀rù
Àwọn míràn lè máa gbé bẹ́ẹ̀
Ibi gíga l'ọkàn mi nfẹ́.
3
Mo fẹ́ kí ngà ju ayé lọ
B'Éṣù tilẹ̀ ngbógun tì mí
Mo nfi gbàgbọ́ gbọ́ orin náà
Tí àwọn mímọ́ nkọ lókè.
4
Mo fẹ́ dé 'bi gíga jùlọ
Nínú ògo dídán jùlọ
Mo ngbàdúrà kí nlè dé bẹ́ẹ̀
Olúwa mú mi dé 'lé náà.
5
Fà mí lọ sí ibi gíga
Láìsí Rẹ nkò ní lè dé 'bẹ̀
Fà mí títí d' òkè ọ̀run
Kí nkọrin lát' ibi gíga.
Àmín.