Hymn 27
Ilé kan wà t'Ọlọ́run f'ìfẹ́ Rẹ̀ hàn
Ilé kan wà t'Ọlọ́run f'ìfẹ́ Rẹ̀ hàn
Ilé rere tó nṣàn fún wàrà àt' oyin;
O sì p'àwọn T'irè pé kí nwọ́n mọ 'lé náà
Kí nwọ́n sì gbé nílé Olúwa.
Ẹ̀yin t' a' ràpadà,
(Ẹni ràpadà gbọ́ àṣẹ Kristi).
Má bẹ̀rù! yan lọ wọ́nù 'lé náà fún ìní
Wọ́nù rẹ̀, gbàt' ìgbì Jọ́dánì' dúró
(Wo o n'ìgbàgbọ́, gbàt' ìgbì Jọ́dánì'dúró)
Wọ́nù 'lé t'Olúwa fi fún ọ.
Àjàrà, rẹ̀ so èso dídùn púpọ̀
Àwọn igi ọ̀pẹ rẹ̀ so jìgbìnnì,
Àwọn ìṣun omi rẹ̀ mú 'lé náà l'ọ́ràá
Níbi nwọ́n nrin nílé Olúwa.
Nílé náà oor'-ọ̀fẹ́ ṣẹ́gun gbogb' ọ̀tá
Àlàáfíà Kristi ṣẹ́gun gbogbo ibi:
Ìfẹ́ Ọlọ́run mú ọkàn gbogbo gbóná,
Nílé t'a gbékelé Olúwa.
Nílé náà níbití 'mọ́lẹ̀ kò dẹ́kun,
Àt'orin ayọ̀ t'áńgẹ́l' fẹ́ láti gbọ́;
Nwọ́n nwò Kristi, nwọ́n kò sì bẹ̀rù ibi kan
Kò sí 'bẹ̀rù nílé Olúwa.
Níhìn, lókè l'àó jogún ilé náà,
Krist' wá s' ayé k'a lè d' ẹni ìbùkún;
Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ dájú, pé a ó wọnú ìsinmi;
'Gbàt' agbẹ́kẹ̀l' ọ̀rọ̀ Olúwa.
Àmín.