Hymn 29
Ní àṣẹ t'ọba Bẹliṣásà pé f'àwọn 'jòyè rẹ̀
Ní àṣẹ t'ọba Bẹliṣásà pé f'àwọn 'jòyè rẹ̀
Wọ́n nfi ago wúrà mutí, b'Ìwé Òtítọ́ ti wí;
Ní òru, bí nwọ́n ti nmú àmuyò l'áfin Ọba
Ìjì ńlá sì mú gbogbo wọ́n.
Ọwọ́ lára ògiri ni
Ọwọ́ lára ògiri ni
Ọwọ́ lára ògiri ni
Ọwọ́ Ọlọ́run lọ nkọ̀wé (Lára ògiri)
Àkọsílẹ̀ náà kò tó ni! tàbí a kò lè gbàgbọ́!
Nígbà t'Ọwọ́ Ọlọ́run nkọ̀wé? (lára ògiri).
Wo Dáníẹ́lì ìgbèkùn, bó ti fi 'gbóiyà dúró;
Ó bá alágbìdi ọba náà wí f'àṣìṣe rẹ̀ yìí;
B'ó ti nkà àkọsílẹ̀ náà, ó jẹ́ ìparun wọ́n,
Tórí 'jọba náà ti d'ópin l'ọ̀rọ̀ ògiri náà wí.
Wo 'gbàgbọ́, akíkanjú on' gbóiyà láti ṣ'ètò
Tí Ẹ̀mí Mímọ́ fún Dáníẹ́lì - èyí tí agbára rẹ̀,
Ní 'lé rẹ̀ ní Jùdéà, tàbí n'ílé ìgbèkùn
Ó mọ ọwọ́ Ọlọ́run rẹ̀ dájú lára ògiri.
Bẹ́ẹ̀ l'a nkọ àwọn 'ṣe wá - Ọwọ́ kan nkọ nísinsìyí;
Ọmọ f'ọkàn rẹ fún Kristi, sì tẹríba f'àṣẹ Rẹ̀;
Nítorípé ọjọ́ mbọ̀, yóò dé fún ẹnikọ̀ọ̀kan
Tí a ó kọ ìdálẹ́bi ẹlẹ́sẹ̀ sára ògiri.
Àmín.