Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 3

Ọkàn mi yin Olúwa lógo

1

Ọkàn mi yin Olúwa lógo,

Ọba ìyanu t'Ó wá mi rí:

'Un ó l'agogo ìyìn y'ayé ká

'Un ó sì f'ìfẹ́ Atóbi-jù hàn.

CHORUS

Olúwa, ọpẹ́ ni fún O

Fún oore-ọ̀fẹ́ t'Ó fi yàn mí,

Jọ̀wọ́ dì mí mú títí d'ópìn

Kí nlè jọba pẹ̀lú Rẹ l'ókè.

2

Bí ẹranko l'èmí bà ségbé

Bíìkòṣe ti Oyígíyigì;

Láìròtẹ́lẹ̀ l'Ẹ̀mí Mímọ́ dé

T'Ó f'èdè titun sí mi l'ẹ́nu.

3

Ayọ̀ ọkàn mi kò ṣe ròyìn

L'ọ́ọ̀rọ̀, l'ọ́sàn, l'ógànjó òru;

Gbàt' Ẹ̀mí Mímọ́ ti dé 'nú mi

Mo ńkọrin ọ̀run lójojúmọ́.

4

Jésù ti là mí lójú ẹ̀mí,

Mo sì f'etí gbọ́hùn ìjìnlẹ̀

Ó nsé fàájì nínú ọkàn mi;

Kíni nbá fi fún Olùgbàlà?

5

Ẹm' ó ṣògo nínú Olúwa

K'èmí má bàá di aláìmọ̀rẹ́;

B'Ó ti pè mí ìyanu l'ó jẹ́

Àwọn áńgẹ́lì d'olùfẹ́ mi.

6

Mo dámùrè láti sin Jésù

Láì f'ọ̀tá pè lárin ayé yìí;

Níbikíbi t'Ó bá ntọ́ mi sí

Ó dájú kò ní jẹ́kí nDàmú.

7

Bí mbá parí 'rè-ìje l'áyé,

Olùgbàlà, má jẹ́ kí npòfo;

Ní wákàtí náà jẹ́kí ngbọ́ pé,

Bọ́ sínú ayọ̀ ayérayé.

Àmín.