Hymn 30
Mo ní láti ní O, Jésù
1
Mo ní láti ní O, Jésù
Nkòjẹ́ dá ọ̀nà yìí rìn
Mo nfẹ́ rí O nítòsí mi;
Fi ọwọ́ Rẹ yí mi ká.
CHORUS
Èmi k' yóò bẹ̀rùkẹ̀rù
Tọ́ mi síbi t'Ó bá fẹ́
Tayọ̀tayọ̀ l'èmi yóò lọ
Un ó máa tọ 'paṣẹ Rẹ lọ.
2
Mo ní láti ní O, Jésù
Ìgbàgbọ́ mi kò tó nkankan
Ọ̀rọ̀ ìtùnú Rẹ nìkan
Ló lè fún mi l'agbára.
3
Mo ní láti ní O, Jésù
L'Ọ́nà àjò mi s'ọ̀run
Nínú òjò tàbí ìjì
Nínú ogun gbígbóná.
4
Mo ní láti ní O, Jésù
Kí ojú Rẹ máa tọ́ mi
Títí un ó dé odò Jọ́dánì
Tí un ó gúnlẹ̀ sọ́dọ̀ Rẹ.
Àmín.