Hymn 32
Tẹ̀síwájú l'ọ́rọ̀ àkọ́mọ̀nà wá
Tẹ̀síwájú l'ọ́rọ̀ àkọ́mọ̀nà wá
Máa wò iwájú rẹ, má bojuwẹ̀hìn
Àwọsánmọ̀ iná li Àmọ̀nà wá
Bálógun wa ntọ́ wa,, tàní y'ó padà?
Ohunkóhun tó dé, ṣá tẹ̀síwájú
A fẹrẹ dé ilé ìlérí Ọ̀run.
Ọmọ ogun Jésù, ẹ tẹ̀síwájú
Ẹ̀yin ni'yọ̀ ayé, àti ìmọ́lẹ̀
Aláìsàn mbọ̀wá fún ìwòsàn l'ọ́fẹ́
Afọ́jú, amúkùn, gbogbo wọ́n y'ó wá
Kúrò nínú ẹ̀tàn, polówó òtítọ́
Kúrò nín' òkùnkùn, bọ́ sí ìmọ́lẹ̀.
Lát' ògo dé ògo li Ó nmú wá lọ
Nínú ògo ńlá yìí l'a ó pín l'ọjọ́ kan
Ògo t'ó ti pèsè ojú kò ì tí rí
Etí kò sì ti gbọ́, ẹwà ògo náà
Pẹ̀lú 'hàmọ́ra yìí, ẹ tẹ̀síwájú
Títí 'bojú y'ó yà tí ao f'ojú rí.
L'ọ́hùn n'ìlú ògo, ilé gíga mbẹ
Ibùgbé Ọlọ́run, ilé wá dídán
Wúrà ni ìtà rẹ̀, ilẹ̀kùn rẹ̀ ndán
Odò ayọ̀ sì nṣàn n'ìlú náà títí
Níbẹ̀ ọmọ ogun, l'Ẹ̀mí ntọ́ wá lọ
Jẹ́ k'a tẹ̀síwájú b'Olúwa ti wí.
Àmín.