Hymn 33
Gbọ́ b'Ó ti wí 'Èmi kì y'ó gbàgbé rẹ'
1
Gbọ́ b'Ó ti wí 'Èmi kì y'ó gbàgbé rẹ'
Kò sí ohun t'ó lè dáàmú ọkàn mi
Bí mo tilẹ̀ nrin ní àfonífojì
Ìmọ́lẹ̀ aiyérayé kò ní pẹ́ mọ́.
CHORUS
Èmi kì yíó gbàgbé rẹ láí
Mo gbé ọ l'apá, mo f'ọwọ́ mi dì ọ́ mú
Èmi kì yíó gbàgbé rẹ láí
Èmi Olùgbàlà y'ó ṣe 'tọ́jú rẹ.
2
Èmi ó ṣe fi ìmọ̀rẹ mi hàn fún?
Ìfẹ́ àt'ìtọ́jú Rẹ pọ̀ lórí mi
Èmi kì yíó gbàgbé rẹ káàkiri
Kí nwọ́n lè ní ìpín n'nú ìlérí Rẹ.
3
Ngó rọ̀mọ́ ìlérí yìí bí mo ti nlọ
'Èmi kò gbàgbé rẹ, nkò fi ọ sílẹ̀'
Ngó máa tẹ̀síwájú, ngó sì máa kọrin
Bí aiyé nkẹ́gàn mi, Jésù súnmọ́ mi.
4
'Gbàtí mo bá gúnlẹ̀ s'ébúté ògo
T'ìdàmú on 'pọ́njú mi sì kọjá lọ
Y'ó ti dùn tó láti gbọ́hùn Rẹ dídùn
'Kábọ̀ ọmọ rere, s'ínú ayọ̀ rẹ.'
Àmín.