Hymn 34
'Gbàt' àláfíà b'ódò ńṣàn s'ọ́kàn mi
1
'Gbàt' àláfíà b'ódò ńṣàn s'ọ́kàn mi
Tí Jésù lé 'bànújẹ́ lọ
Ohunkóhun tó dé èyí l'orin mi
Pé 'sinmi dídùn dé s'ọkàn mi.
CHORUS
Ó dára ... f'ọkàn mi
Ó dára, ó dára f'ọkàn mi.
2
Bí èṣù fi ìdánwò pọ̀n mí lójú
Ohun kan yìí dá mi lójú
Pé Jésù ti dárí gbogb' ẹ̀ṣẹ̀ mi jì
Ó f'ẹ̀jẹ̀ Rẹ wẹ ọkàn mi mọ́.
3
Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi k'ìṣe díẹ̀ n'nú rẹ̀
Gbogbo rẹ̀ l'a dárí jì mí
A dá Krist' lẹ́bi kò tún s'ẹ́bi fún mi
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
4
Ngó y'ara mi sí mímọ́ fún Olúwa
B'àkókò ikú tilẹ̀ dé
Ẹ̀rù kò sí mọ́ 'tórí 'Wọ o mú mi
Wọ inú ìsinmi dídùn lọ.
5
Ṣùgbọ́n bíbọ̀ Rẹ li èmi ndúró dè
Ìwọ n'ìrètí ọkàn mi
Igbé ariríwo Ọkọ 'yàwó y'ó ta
Ìrètí ìsinmi f'ọkàn mi.
Àmín.