Hymn 35
Olúwa ló pè wá, àwa náà sì ntẹ̀lé
Olúwa ló pè wá, àwa náà sì ntẹ̀lé
O fi ẹsẹ̀ wá lé ọ̀nà tí Ón rìn
B'ó jẹ́ lórí òkè tàbí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ni
Ọ̀nà náà y'ó parí sí ilé ògo
Olúwa ló pè wá àwa ọmọ Tirẹ̀
A ntẹ̀síwájú lábẹ́ àsíá Rẹ
A fẹ́ràn Rẹ púpọ̀, a sì nṣàfẹ́rí Rẹ
A nrin nínú ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.
Olúwa ló pè wá, àwa kò ní bẹ̀rù
B'ọ̀nà kò tilẹ̀ dán, bí ewu sì pọ̀
Ẹ̀mí Rẹ ngbé'nú wá, O sì ntú wá nínú
Àwa y'ó máa tẹ̀lé, láìbojúw' ẹ̀hìn
Olúwa ló pè wá, a ó máa kọrin lọ
B'ìdánwò tilẹ̀ dé, àt'ìyèméjì
'Tẹ̀síwájú, w'ókè' má kà ìpọ́njú sí
Àwọn ọmọ Síónì, ntẹ̀lé Ọba wọ́n.
Olúwa ló pè wá, n'íbẹ̀rẹ̀ aiyé wá
O dá ẹ̀mí titun s'ínú ọkàn wá
A rí f'aiyé sílẹ̀, pẹ̀lú ìgbádùn rẹ̀
Láti dápọ̀ mọ́ àwọn ọm' Ọlọ́run
Olúwa ló pè wá, t'ó sọ wá dọmọ Rẹ
Àwa ngbẹ́kẹ̀ wá lé, O sì mbùkún wá
Síb' ìtura ọkàn, omi tútù yọ̀yọ̀
Níbẹ̀ l'ó ntọ́ wá sí títí dé 'lé wá.
Àmín.