Hymn 37
Mo ńsin Jésù t'ó jíǹde, ọ̀kanna ni lónìí
1
Mo ńsin Jésù t'ó jíǹde, ọ̀kanna ni lónìí
Mo mọ̀ pé Ó mbẹ l'áyè, bí nwọ́n tilẹ̀ nkẹ́gàn
Mo rí ọwọ́ àánú Rẹ, mo ngbọ́hùn Rẹ dídùn
Nígbà mo fẹ́ 'rànwọ́ Rẹ, Ó mbẹ n'ítòsí.
CHORUS
Ó mbẹ l'áyè, Ó mbẹ l'áyè síbẹ̀
Ó mbà mí rìn lójojúmọ́ lí ọ̀nà tóró yìí
Ó mbẹ l'áyè, láti mú 'gbàlà Wá
B'ó bá fẹ́ mọ̀ p'Ó mbẹ l'áyè?
Ó ngbé 'nú ọkàn mi.
2
Ní àyíká mi gbogbo mo nrí ìtọ́jú Rẹ
Bí arẹ́ tilẹ̀ mú mi èmi kò jẹ́ dáàmú
Mo mọ̀ yíó mú mi la gbogbo ìdánwò ja
Ọjọ́ ìfarahàn Rẹ y'ó dé láìpẹ́.
3
Onígbàgbọ́, bú s'ayọ̀, gbé orin 'yìn sókè
Kọrin Halélúyà sí Jésù Kristi Ọba
Ìrètí àti 'rànwọ́ àwọn tí npọ́gbẹ Rẹ
Kò s'onínúure bíi Rẹ l'áyè, l'ọ̀run.
Àmín.