Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 38

Ilé kan mbẹ t'ó dára jùlọ

1

Ilé kan mbẹ t'ó dára jùlọ

A lè f'ìgbàgbọ́ ní ilé náà

Níbití Bàbá ndúró dè wá

Láti fún wá n'íbùgbé níbẹ̀.

CHORUS

Pẹ̀l'ayọ̀.....nígbàṣe

L'a ó pàdé l'ébúté dídán wá

Pẹ̀l'ayọ̀....nígbàṣe

L'a ó pàdé l'ébúté dídán wá.

2

A ó kọrin l'ébúté dídán wa

Orin t'àwọn alabukunfún

Kò ní s'ìbànújẹ́ fún wa mọ́

Kìkì 'sinmi dídùn àt'ayọ̀.

3

A ó kọrin ìyìn sí Bàbá wá

Fún oore ọ̀fẹ́ Rẹ lórí wá

Fún ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ tí Ọmọ Rẹ

Àt'ìbùkún t'a kò lè kà tán.

Àmín.