Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 39

Gbọ́ ìró ayọ̀ dídùn

1

Gbọ́ ìró ayọ̀ dídùn

Pé Jésù ngbà ni là

Kéde rẹ̀ jákèjádò

Pé Jésù ngbà ni là

Tan ìhìn ayọ̀ náà ká

Lór'òkè on pẹ̀tẹ́lẹ̀

Kéde rẹ̀ kíkankíkan

Pé Jésù ngbà ni là.

2

Sọ fún àwọn tó jinnà

Pé Jésù ngbà ni là

F'àwọn tó wà nítòsí

Pé Jésù n gbà ni là

Sọ fún gbogbo ẹlẹ́ṣẹ̀

Ọ̀rẹ́ àt'ìbátan rẹ

Sọ ti ìdásílẹ̀ yìí

Pé Jésù ngbà ni là.

3

Kọrin ìràpadà náà

Pé Jésù ngbà ni là

Ó ti kú Ó sì jíǹde

Pé Jésù ngbà ni là

Kọrin náà l'óhùn jẹ́jẹ́

Fún ọkàn tó nwá àánú

Kọ orin ìṣẹ́gun wá

Pé Jésù ngbà ni là.

4

Kí gbogbo wa kọrin náà

Pé Jésù ngbà ni là

Kí gbogb'aiyé bú s'ayọ̀

Pé Jésù ngbà ni là

Ọ̀fẹ́ ni ìgbàlà náà

Ìgbàlà kíkún sì ni

Orin ìṣẹ́gun l'èyí

Pé Jésù ngbà ni là.

Àmín.