Hymn 4
Baba, a wa yìn Ó o
1
Awa dúpẹ́ pé O dá wa sí,
A rí ọwọ́ ìbùkún Rẹ ní ayé wa ṣe,
Baba, a wa f'ìrẹ̀lẹ̀ jọ́sìn fún O o,
Èdùmàrè.
CHORUS
Baba, a wa yìn Ó o,
Baba, a wa yìn Ó o,
Baba, a wa f'ìrẹ̀lẹ̀ jọ́sìn fún O o,
Èdùmàrè.
2
O ṣèlérí ìrọ̀rùn nínú ohun gbogbo,
O pèsè ilé ìjọsìn ní àkókò yìí,
Baba, a wa f'ìrẹ̀lẹ̀ jọ́sìn fún O o;
Èdùmàrè.
3
Àw' ọmọ Rẹ tí O mi sí o láti ṣe èyí fún O,
F'àlàáfíà àt'ẹ̀mí gígùn àt'ayọ̀ fún wa;
Baba, a wa f'ìrẹ̀lẹ̀ jọ́sìn fún O o,
Èdùmàrè.
4
Àw' ọmọ Rẹ tí O mi sí o láti ṣe èyí fún O,
F'ìjọba ọ̀run síkẹ́ wa o níkẹyìn ayé wa;
Baba, a wa f'ìrẹ̀lẹ̀ jọ́sìn fún O o,
Èdùmàrè.
5
Ẹ̀yin ogun ọ̀run, sọ̀kalẹ̀, ẹ ya 'hìn sí mímọ́,
Ẹ fi ìbéèrè wa fún wa l'àkókò gbogbo;
Baba, a wa f'ìrẹ̀lẹ̀ jọ́sìn fún O o,
Èdùmàrè.
Àmín.