Hymn 40
Sọ ìtàn ti Jésù fún mi
1
Sọ ìtàn ti Jésù fún mi
Tí mo fẹ́ràn;
Gbogb'ohun tí bá sọ fún mi
B'Ó mbẹ níhìn
Tí ẹbá ọ̀nà
Àti t'òkun,
Ìtàn ti Jésù
Sọ wọ́n fún mi.
2
Kò sọ bí àwọn ọmọdé
Ti yí I ká;
Kí èmi lè rò pé 'bùkún Rẹ̀
Bá lórí mi:
Ọ̀rọ̀ inúre
Iṣẹ́ oore
N'nú mọ́lẹ̀ ìfẹ́
Ojú Jésù.
3
Mbá lè bá ẹgbẹ́ ọmọdé
Wọ inú ìlú
Pẹ̀lú ẹ̀ka igi ọ̀pẹ
Li ọwọ́ mi;
Bí akéde Rẹ̀
Ni mbá kọrin
Wípé, Hósánà!
Jésù jọba!
4
Sọ fún mi bí ìgbì òkun
Tí nyì rìdì
Bí ìjì ti ndáàmú ọkọ̀
Ní Gálílì
Àti bí Jésù
L'óhùn jẹ́jẹ́
Ti bá ìgbì wí,
T'ìjì sì pa.
Àmín.