Hymn 42
Kò s'ọ́rẹ́ bíi Jésù onírẹ̀lẹ́
1
Kò s'ọ́rẹ́ bíi Jésù onírẹ̀lẹ́
Kò s'ọ́rẹ́ bí ti Rẹ̀
Kò s' oníṣègùn tó lè w'ẹ̀ṣẹ̀ sàn
Kò s'ọ́rẹ́ bí ti Rẹ̀.
CHORUS
Jésù mọ gbogbo 'jàkàdì wá
Y'ó rán wa lọ́wọ́ dé òpin
Kò s'ọ́rẹ́ bíi Jésù onírẹ̀lẹ́
Kò s'ọ́rẹ́ bí ti Rẹ̀.
2
Kòs'ọ́rẹ́ tó ga bíi Rẹ̀ ní mímọ́
Kò s'ọ́rẹ́ bí ti Rẹ̀
Kò s'ọ́rẹ́ tó n'írẹ̀lẹ̀ bí ti Rẹ̀
Kò s'ọ́rẹ́ bí ti Rẹ̀.
3
Kò s'àkókò kan tí kò súnmọ́ wá
Kò s'ọ́rẹ́ bí ti Rẹ̀
Nínú 'dánwò y'ó máa tú wá nínú
Kò s'ọ́rẹ́ bí ti Rẹ̀.
4
Àwọn t'ó gbàgbọ́ mọ̀ L'Ẹni rere
Kòs'ọ́rẹ́ bí ti Rẹ̀
Àwọn t'ó wà l'óde ngbọ́hùn 'fẹ́ Rẹ̀
Kòs'ọ́rẹ́ bí ti Rẹ̀.
5
Ẹ̀bùn kan ha wà tó ju Jésù lọ?
Kò s'ọ́rẹ́ bí ti Rẹ̀
Y'ó ha kọ̀ fún wá k'á n'ílé l'ọ̀run?
Kò jẹ́ kọ̀! Kò jẹ́ kọ̀!
Àmín.