Hymn 43
Ọkàn àt'ohùn mi
1
Ọkàn àt'ohùn mi
Ni ngó fi yin Jésù
Kí gbogb' aiyé yin Olúwa
Ó njọba ní gbogbo
Aiyé àti ọ̀run
Ẹnit' ó dá ohun gbogbo.
2
Ó wá bí ìránṣẹ́
Nínú àwò ẹ̀dá
Ó gba ègún wá s'orí Rẹ̀
Ó fi 'ra Rẹ̀ rúbọ
Ó ta 'jẹ̀ Rẹ̀ sílẹ̀
Láti sọ wá d'ómìnira.
3
Aṣẹ́gun ti jíǹde
Ó bórí ọ̀tá Rẹ̀
Ó sì dì wọ́n ní ìgbèkùn
Ó fọ́ ìjọba wọn
Ó mú wọ́n jẹ́wọ́ pé
Kristi l'Ọba gbogbo aiyé.
4
Nínú àánú Rẹ ńlá
L'ó fi njọba l'aiyé
Nínú ọgbọ́n àt'òdodo
Ẹni tó Jésù wá
Y'ó tọ́ ìfẹ́ Rẹ̀ wò
Y'ó rí 'gbàlà ńlá gbà l'ọ́fẹ́.
5
Ọba àlàáfíà
Kí ìjọba Rẹ dé
Kí gbogb' aiyé rí ògo Rẹ
Títí òdodo Rẹ
Àti ìwà mímọ́
Y'ó gbìlẹ̀ nínú aiyé yìí.
Àmín.