Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 45

Má jẹ́ k'ọ̀rọ̀ náà kọjá lọ

1

Má jẹ́ k'ọ̀rọ̀ náà kọjá lọ,

K'o sì d'ojú sí 'mọ́lẹ̀ yìí

Ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣ'ọkàn rẹ payà,

Gbà 'gbàlà l'álẹ́ yìí.

CHORUS

Kí ló ṣe tí kò j'álẹ́ yìí;

Kí ló ṣe tí kò j'álẹ́ yìí

(Tí kò j'álẹ́ yìí, Jẹ́ álẹ́ yìí)

O ha nfẹ́ ìgbàlà, Jẹ́ kó j'álẹ́ yìí

(O nfẹ́ ìgbàlà, O nfẹ́ ìgbàlà,

Jẹ́ kó j'álẹ́ yìí).

2

Ọ̀run ọ̀la lè ṣàìmọ́

Láti bùkún ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ

Àkókò náà dé, ọlọ́gbọ́n

Gbà 'gbàlà l'álẹ́ yìí.

3

Àánú Ọlọ́run wà ṣíbẹ̀

'Wọ k'yó wá sí 'nú 'fẹ́ Rẹ

Kọ ìwà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀

Gbà 'gbàlà l'álẹ́ yìí.

4

Aiyé kò n'ádùn kan fún

Kò sí ohun rere kan níbẹ̀

Jọ̀ọ́ tọ́ aiyé Kristíánì wò,

Gbà 'gbàlà l'álẹ́ yìí.

5

Olúwa k'yíó kọ̀ ọ́ sílẹ̀

Bí o bá f'ọkàn rẹ fún

Gbààgbọ́ iṣẹ́ náà ti parí

Gbà 'gbàlà l'álẹ́ yìí.

Àmín.