Hymn 47
Ẹ̀mí Mímọ́ dé l'ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́stì
1
Ẹ̀mí Mímọ́ dé l'ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́stì
Pẹ̀lú agbára ìsọjí
Ìfihàn Rẹ n'nú àwọn tó gbàgbọ́
Jèrè ọpọ̀ ọkàn fún Kristi
Ìjọ Kristi tàn ká gbogbo ayé
Wọ́n nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà
Ọpọ̀ wọ́n sì kú bí ajẹ́rìíkú
Wọ́n fi gbàgbọ́ lọ sí 'ṣẹ́gun.
CHORUS
Wá Ẹ̀mí Mímọ́, Òkùnkùn sú,
Mú wá sọjí, fi agbára ńlá rẹ kún wá
Dá 'ná ìfẹ́ Rẹ sí ọkàn wá
Wá Ẹ̀mí Mímọ́, wá sọ wá jí lónìí.
2
'Gbàt' òkun ẹ̀ṣẹ̀ borí ayé
Ẹ̀mí Mímọ́ tan 'mọ́lẹ̀ Rẹ
Olódodo y'ó yè nípa 'gbàgbọ́
Ni 'wọ́n nkédè jákèjádò
Ọlọ́run sì rán ọpọ̀ ìsọjí
Iná àdúrà njó géré
A nfẹ́ irú ìsọjí bí èyí
Fún 'pè níjà àkókò yìí.
Àmín.