Hymn 48
Kristi Olùgbàlà wá n'nú ògo
1
Kristi Olùgbàlà wá n'nú ògo
Láti gb'ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú ẹgbẹ́
L'orí Rẹ ni a fi adé ẹ̀gún;
Ní Kálfárì lótì ru ẹ̀bi mi.
CHORUS
Ón gbé l'ókè, Ón gbé l'ókè
Bórí ẹ̀ṣẹ̀ àti ọmọ ogun rẹ̀
Ón gbé l'ókè, Ón gbé l'ókè
L'ọjọ́ kan ó n padà bọ̀ wá.
2
Ó jíǹde nínú ikú 'bànújẹ́
Láti gbé n'nú ayọ̀ àti ìfẹ́
Ón padà bọ̀ li ọjọ́ ayọ̀ kan
Láti k'àwọn ọmọ Rẹ re 'lé l'ókè.
3
Ọkàn arẹ́ sá tọ́ Jésù lónìí
Gbà ìràpadà tó fi fún ọ,
Sáà wò Jésù kí o gbà ìbùkún
Ìyè mbẹ ayọ̀ mbẹ àti 'ṣẹ́gun.
Àmín.