Hymn 49
Ojú mi ti rí ògo ìpadàbọ̀ Olúwa
1
Ojú mi ti rí ògo ìpadàbọ̀ Olúwa
Yíó ṣẹ́gun ikú àti gbogbo ipá agbára rẹ̀
Ó tú àwọn olóòótọ́ nínú ìmọ́lẹ̀ ògo Rẹ̀
Òtítọ́ Ó nṣìwájú.
CHORUS
Ògo, ògo halélúyà;
Ògo, ògo halélúyà,
Ògo, ògo halélúyà,
Ìjọ ntẹ̀síwájú.
2
Mo rí nínú ògo ẹgbẹgbẹ̀rún ìmọ́lẹ̀ ọ̀run
Lórí ìtẹ́ ẹwà ìwà mímọ́ ti ìgbà àsálẹ́
Mo lè ka òdodo àti ẹwà ìwà mímọ́ Rẹ̀
Àwa ntẹ́ síwájú.
3
Oùn agogo ọ̀run ndùn wípé ká tẹ̀síwájú
Ó nṣọ fún gbogbo ènìyàn pé ìdájọ́ Rẹ̀ fẹ́ dé,
Múra tán ìwọ ọkàn mi k'ó sì bú s'orin ayọ̀
Àwa ntẹ̀síwájú.
Àmín.