Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 5

Ẹ fi 'bùkún fún Ọlọ́run

1

Ẹ fi 'bùkún fún Ọlọ́run,

Olódùmarè ni;

Ẹni t'Ó dá ayé,

Àt' ohun inú rẹ̀,

Fún ìkẹ́ ọmọ ènìyàn

Ìyìn, ọlá àt'ògo f'Olúwa!

2

Olùbùkún àt'Ọlọ́gbọ́n,

'Wọ Ológo l'à ńyìn;

Ẹni t'Ó dá wa sí,

Tó bùkún iṣẹ́ wa,

Tó sì ngbé orí wa ga,

Ìyìn, Ọlá àt'ògo f'Olúwa.

3

'Gbàtí ẹ̀ṣẹ̀ wa fi wá sùn,

T'ọkàn wa bàjẹ́,

Igbé wa ké t'Ó lọ;

O sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ náà;

O sì dá wa ní ìdè.

Ìyìn, ọlá àt'ògo f'Olúwa!

4

Ìyìn ló yẹ Kristi Ọba;

Ẹ dé l'ádé púpọ̀;

Ẹni t'Ó fi ìfẹ́,

'Mọ́lẹ̀ àt'ẹ̀mí Rẹ̀

Mú 'ràpadà wá s'áyé;

Ìyìn, ọlá àt'ògo f'Ọlọ́run!

5

B'írùn mi jẹ́ kíkí ahọ́n,

Kò tó fún ìyìn Rẹ;

B'Ọlọ́run tilẹ̀ ga

Jù gbogbo ìyìn lọ,

Síbé un ó kọrin ọpẹ́;

Ìyìn, ọlá àt'ògo f'Olúwa!

Àmín.