Hymn 50
Gbọ́ orin àwọn Ańgẹ́lì
1
Gbọ́ orin àwọn Ańgẹ́lì
Yíká ìtẹ́ Rẹ
Gbogbo wọ́n nlù dùrù wúrà
L'ọ̀sán àt'òru
Ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn mímọ́
Njẹ́wọ́ pé Jésù l'Ọba.
2
Ìwọ tí ngbé n'nú mọ́lẹ̀ ńlá
T'ẹ̀dá kò lè wò
Síbé ìwọ nfẹ́ láti gbọ́
Orin ìyìn wá
A bè lé mọ́ p'Ó súnmọ́ wá
Láti gbọ́ àdúrà wá.
3
A f'ara wá rúbọ fún O
Nínú ilé Rẹ
Gbà ọkàn wá, ọwọ́, ẹsẹ̀,
Àti ohùn wá
Yà wọ́n sí mímọ́ fún lílò
L'aiyé yìí àti l'ọ̀run.
4
Ògo, ọlá àti ìyìn
L'a ó máa fi fún O
Baba, Ọmọ àti Ẹ̀mí
Mẹ́ta n'nú ọ̀kan
Ọpọ̀ 'bùkún t'ó nfi fún wá
L'àwa tún nfun O padà.
Àmín.