Hymn 6
Ìwọ tó lè wá la ó máa sìn títí
1
Ìwọ tó lè wá la ó máa sìn títí
Olúwa Oloore wá;
Ìwọ tó ńṣọ́ wá n'nú ìdánwò ayé,
Mímọ́, l'ógo Ọlá Rẹ,
CHORUS
Baba, Ìwọ l'a ó máa sìn,
Baba, Ìwọ l'a ó máa bọ̀,
Ìwọ tó fẹ́ wa l'a ó máa sìn títí,
Mímọ́ l'ógo Ọlá Rẹ.
2
Ìwọ tó ńsúre s'ohun t'a gbìn s'áyé
T'ayé fi ńrohun jẹ o;
Àwọn tó múra láti máa ṣ'òótọ́,
Wọ́n tún nyọ̀ n'nú iṣẹ́ Rẹ.
3
Ìwọ tó nf'àgàn l'ọ́mọ tó ńpè ránṣẹ́
Nínú ọlá Rẹ tó ga;
Ẹni t'ó ti ṣ'aláìléso sì dúpẹ́
Fún 'ṣẹ́ ògo ọlá Rẹ.
4
Ẹni t'ebi ńpa lè rí ayọ̀ nínú
Agbára ńlá Rẹ tó ga,
Àwọn tó ti nwójú Rẹ fún àánú
Wọ́n tún nyọ̀ n'nú iṣẹ́ Rẹ.
5
F'àlàáfíà Rẹ fún ìjọ Rẹ l'áyé
K'oore-ọ̀fẹ́ Rẹ máa ga.
K'àwọn ẹni Tìrẹ kó máa yọ̀ títí
Nínú ògo iṣẹ́ Rẹ.
Àmín.