Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 7

Èmi y'ó san ore o f'Ọlọ́run mi

1

Èmi y'ó san ore o f'Ọlọ́run mi

Èmi y'ó san ore o f'Ọlọ́run mi

Ẹni dá mi sí o látesìwá

Ẹni dá mi sí o látesìwá

Fún jíjẹ, fún mímu, t'ó nb'àṣírí mi

Fún ìpèsè lójojúmọ́ l'ọ́nà àrà jábúrátà

Kò jẹ́ k'áyé yọ mí, lójú ẹlẹ́gàn, ayé mi Dára

Èmi y'ó f'ore hàn f'Ọlọ́run mi.

2

Ẹ jẹ́k' aṣajoyọ̀ f'ọpẹ́ òní

Ẹ jẹ́k' aṣajoyọ̀ f'ọpẹ́ òní

Ẹni bá m'oore Rẹ wá ká s'ọpẹ́

Ẹni bá m'oore Rẹ wá ká s'ọpẹ́

F'orí wa tó dára, tí Ó nbùkún fún wa

Ó fi'gbàlà dá wá l'ọ́lá, Ó npèsè ohun gbogbo

Kò jẹ́k' àwa ṣègbé, lójú ẹlẹ́gàn, Ó gbé wa ró o

Ẹni 'nú rẹ̀ bá dùn jẹ́ kó yọ̀ o.

3

Èmi y'ó yin Jésù, Ọba Ògo

Èmi y'ó yin Jésù, Ọba Ògo

Olú ṣeun àrà, Ó m'ayọ̀ mi kún

Olú ṣeun àrà, Ó m'ayọ̀ mi kún

Ó dá mi l'ọ́lá o, Ó tún pè mí l'ọ́mọ

Ó f'ohun àtàtà lé mi lọ́wọ́, ohun ìjìnlẹ̀ tó dájú

Kò jẹ́k' ẹ̀rù bà mí, lójú ẹlẹ́gàn ó yé mi sí o

Èmi y'ó yin Jésù, Ọba ògo.

4

Ẹ jẹ́ k'á fọpẹ́ hàn f'Ọlọ́run wá

Ẹ jẹ́ k'á fọpẹ́ hàn f'Ọlọ́run wá

Ẹni dá wá sí o d'ojó òní

Ẹni dá wá sí o d'ojó òní

Ó fún wá l'ọ́gbọ́n o, Ó tún pè wá s'agbo

Ọmọ Ìgbàlà múra gírì, kò má fòyà rárá rárá

Dúró nínú 'gbàgbọ́, l'ọjọ́ ayé rẹ, á dára fún ọ

Ẹ jẹ́k'á fọpẹ́ hàn f'Ọlọ́run wá.

Àmín.